Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Persecution

270 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Má ṣe jìnnà sí mi, nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

  2. Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká; àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.

  3. Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri, tí ń ké ramúramù.

  4. A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀. Ọkàn mi sì dàbí i ìda; tí ó yọ́ láàrín inú mi.

  5. Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi; ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

  6. Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀.

  7. Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi; àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.

  8. Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

  9. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi. Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!

  10. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà, àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.

  11. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún; kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

  12. Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi. Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.

  13. Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.

  14. Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.

  15. Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọ́n ju irun orí mi lọ, púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run. A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí.

  16. Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run; ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.

  17. Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun; má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi, Ọlọ́run Israẹli.

  18. Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi.

  19. Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi; àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;

  20. nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run, àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

  21. Nígbà tí mo sọkún tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

  22. nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà, àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.

  23. Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi, mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

  24. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa, ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ, dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.

  25. Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀, má ṣe jẹ́ kí n rì; gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, kúrò nínú ibú omi.