Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Persecution: Of Jesus

152 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Of Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

  2. Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

  3. Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.

  4. Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

  5. Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

  6. Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀ yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,

  7. Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi?

  8. Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́.

  9. Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn; mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn.

  10. Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.

  11. “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa; jẹ́ kí Olúwa gbà á là. Jẹ́ kí ó gbà á là, nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

  12. Má ṣe jìnnà sí mi, nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

  13. Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká; àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.

  14. Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri, tí ń ké ramúramù.

  15. A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀. Ọkàn mi sì dàbí i ìda; tí ó yọ́ láàrín inú mi.

  16. Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi; ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

  17. Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀.

  18. Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi; àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.

  19. Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

  20. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi. Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!

  21. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà, àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.

  22. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún; kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

  23. Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi. Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.

  24. Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.

  25. Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.