Fò sí àkóónú

Satan

55 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Beelzebub

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Satan

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tiatira, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pè ni ohun ìjìnlẹ̀ Satani, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín,

  2. Kíyèsi i, èmi ó mú àwọn ti Sinagọgu Satani, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké; kíyèsi i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ.

  3. A sì lé dragoni ńlá náà jáde, ejò láéláé nì, tí a ń pè ni Èṣù, àti Satani, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.

  4. O sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.

  5. Nígbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá sì pé, a ó tú Satani sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀.