Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rain

116 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀.

  2. Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.”

  3. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.

  4. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta (600) ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀.

  5. Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

  6. Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i.

  7. Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi.

  8. Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.

  9. Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.

  10. Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn.

  11. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú.

  12. Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù.

  13. Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́.

  14. Ọlọ́run sì wí fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé,

  15. “Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

  16. Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé.

  17. Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.”

  18. Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀:

  19. Mo ti fi òṣùmàrè sí àwọsánmọ̀, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín èmi àti ayé.

  20. Nígbàkígbà tí mo bá mú kí òjò ṣú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní àwọsánmọ̀.

  21. Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run.

  22. Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”

  23. Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrín èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.”

  24. Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, Èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Ejibiti láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí.

  25. Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.”