Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rain: The plague of, upon Egypt

7 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The plague of, upon Egypt

  1. Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.”

  2. Nígbà tí Mose gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, Olúwa rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bùsi orí ilẹ̀. Olúwa rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Ejibiti.

  3. Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bùsi orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì burú jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Ejibiti ti di orílẹ̀-èdè.

  4. Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú.

  5. Ilẹ̀ Goṣeni ni ibi ti àwọn Israẹli wà nìkan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé.

  6. Nígbà náà ni Mose jáde kúrò ni iwájú Farao, ó kúrò ni àárín ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Olúwa, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́.

  7. Nígbà tí Farao rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣì sé àyà wọn le.