Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rain: David delivered by

6 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ nípa David delivered by

  1. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dafidi jẹ ọba lórí Israẹli, gbogbo àwọn Filistini sì gòkè wá láti wá Dafidi; Dafidi sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódi.

  2. Àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Refaimu.

  3. Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Filistini bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Filistini lé ọ lọ́wọ́.”

  4. Dafidi sì dé Baali-Perasimu, Dafidi sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọ̀tá mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baali-Perasimu.

  5. Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn.

  6. Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní òkè Perasimu yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní àfonífojì Gibeoni— láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀, yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.