Skip to content

Pharaoh

138 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Pharaoh

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí àwọn ìjòyè Farao sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú Farao, wọ́n sì mú un lọ sí ààfin.

  2. Ní gbogbo àkókò wọ̀nyí, àwọn ará Midiani ta Josẹfu ní Ejibiti fún Potifari, ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao, tí í ṣe olórí ẹ̀ṣọ́.

  3. Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”

  4. Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.”

  5. Láàrín ọjọ́ mẹ́ta Farao yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbé ọtí fún un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá.

  6. Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n.

  7. Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa fi ago lé Farao ní ọwọ́,

  8. Josẹfu gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti àti Kenaani ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Farao.

  9. Nítorí náà Josẹfu ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Ejibiti fún Farao, kò sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù ní Ejibiti tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Farao,

  10. Wọ́n dá á lóhùn pé, “O ti gbà wá là, ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Farao.”

  11. Nítorí náà Josẹfu sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Ejibiti, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òní olónìí pé, ìdákan nínú ìdámárùn-ún ìre oko jẹ́ ti Farao, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Farao.

  12. Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé, “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”

  13. Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá.

  14. Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ.” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀.

  15. Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”

  16. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.”

  17. Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?”

  18. Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Ejibiti rí i pé ìwọ ṣe iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Farao. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì sé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ.

  19. Lẹ́yìn náà, kí o sọ fún Farao pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Israẹli ní àkọ́bí ọmọ mi ọkùnrin,

  20. Lẹ́yìn náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ”

  21. Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.”

  22. Nígbà náà ni Farao sọ pé, “Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsin yìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ.”

  23. Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn ti ń ṣe alábojútó iṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn.

  24. Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Èyí ni ohun tí Farao sọ, ‘Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́.

  25. Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao yàn lára ọmọ Israẹli ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?”