Skip to content

Rephaim

8 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: valley

31.7500, 35.2200 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Rephaim

  1. Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí àfonífojì Beni-Hinnomu ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúúsù ti Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí àfonífojì Hinnomu tí ń bẹ ní ìpẹ̀kun àfonífojì Refaimu ní ìhà àríwá.

  2. Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí àfonífojì Beni-Hinnomu, àríwá àfonífojì Refaimu. O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí àfonífojì Hinnomu sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jebusi, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-Rogeli.

  3. Àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Refaimu.

  4. Àwọn Filistini sì tún gòkè wá, wọ́n sì tan ara wọn kalẹ̀ ní àfonífojì Refaimu.

  5. Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu, ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí àfonífojì Refaimu.

  6. Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dafidi wá lọ sí orí àpáta nínú ihò Adullamu, nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Filistini sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Refaimu.

  7. Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti àfonífojì Refaimu;

  8. Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn irúgbìn tí ó dúró jọ tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀— àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Refaimu.