Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tribe Of Benjamin

107 ẹsẹ · 35 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ọmọ Benjamini ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹsànán.

  2. Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  3. àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

  4. akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

  5. akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  6. màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Abidani ọmọ Gideoni.

  7. Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí: tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela; ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli; ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;

  8. ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.

  9. Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí: ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi; ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.

  10. Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Benjamini, ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàrín ti ẹ̀yà Juda àti Josẹfu.

  11. Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jordani, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jeriko ní ìhà àríwá, ó sì forí lé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí aginjù Beti-Afeni.

  12. Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúúsù ní ọ̀nà Lusi (tí í ṣe Beteli) ó sì dé Atarotu-Addari, ní orí òkè tí ó wà ní gúúsù Beti-Horoni.

  13. Láti òkè tí ó kọjú sí Beti-Horoni ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Baali (tí í ṣe Kiriati-Jearimu), ìlú àwọn ènìyàn Juda. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.

  14. Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jearimu ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nefitoa.

  15. Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí àfonífojì Beni-Hinnomu, àríwá àfonífojì Refaimu. O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí àfonífojì Hinnomu sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jebusi, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-Rogeli.

  16. Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni-Ṣemeṣi, ó tẹ̀síwájú dé Geliloti tí ó kọjú sí òkè Adummimu, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Òkúta Bohani ọmọ Reubeni.

  17. Ó tẹ̀síwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Araba, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù.

  18. Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Hogla, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jordani ní gúúsù. Èyí ni ààlà ti gúúsù.

  19. Odò Jordani sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn. Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sàmì sí ìní àwọn ìdílé Benjamini ní gbogbo àwọn àyíká wọn.

  20. Ẹ̀yà Benjamini ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí: Jeriko, Beti-Hogla, Emeki-Keṣiṣi,

  21. Beti-Araba, Semaraimu, Beteli,

  22. Affimu, Para, Ofira

  23. Kefari, Ammoni, Ofini àti Geba; àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

  24. Gibeoni, Rama, Beeroti,

  25. Mispa, Kefira, Mosa,