Fò sí àkóónú

Kiriath-jearim

15 verses · 3 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Kirjath, Kirjath-jearim

31.7700, 34.9900 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Kiriath-jearim

  1. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Israẹli jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta: Gibeoni, Kefira, Beeroti àti Kiriati-Jearimu.

  2. Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu).

  3. Kiriati-Baali (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu) àti Rabba ìlú méjì àti ìletò wọn.

  4. Láti òkè tí ó kọjú sí Beti-Horoni ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Baali (tí í ṣe Kiriati-Jearimu), ìlú àwọn ènìyàn Juda. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.

  5. Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jearimu ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nefitoa.

  6. Ṣela, Haelefi, ìlú Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu), Gibeah àti Kiriati, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn. Èyí ni ìní Benjamini fún ìdílé rẹ̀.

  7. Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí.

  8. Nígbà náà, wọ́n rán àwọn ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí Kiriati-Jearimu wí pé, “Àwọn Filistini ti dá àpótí ẹ̀rí Olúwa padà. Ẹ sọ̀kalẹ̀ wá, kí ẹ gbé e gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ yín.”

  9. Nígbà náà àwọn ará Kiriati-Jearimu wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Abinadabu lórí òkè, wọ́n sì ya Eleasari ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa.

  10. Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati-Jearimu. Gbogbo ilé Israẹli ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùnréré ẹkún sí Olúwa.

  11. Nígbà náà ni Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣihori ní Ejibiti lọ sí Lebo ní ọ̀nà à bá wọ Hamati, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati-Jearimu.

  12. Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù gòkè wá.

  13. Nísinsin yìí, Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jearimu sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jerusalẹmu.

  14. Kiriati-Jearimu, Kefira, àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta (743)

  15. (Bákan náà Uriah ọmọ Ṣemaiah láti Kiriati-Jearimu jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ Olúwa. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremiah ti ṣe.