Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Eleazer
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Nígbà náà àwọn ará Kiriati-Jearimu wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Abinadabu lórí òkè, wọ́n sì ya Eleasari ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa.
Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati-Jearimu. Gbogbo ilé Israẹli ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùnréré ẹkún sí Olúwa.
Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò.
Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun.
Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Mahili: Eleasari àti Kiṣi.
Eleasari sì kú pẹ̀lú àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.