Mahli
A tún mọ̀ ọ́n sí: Mahali
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Mahli
Àwọn ọmọ Merari ni: Mahili àti Muṣi. Ìwọ̀nyí ni ìran Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.
Àwọn ìdílé Merari ni: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni ìdílé Lefi gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.
Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn.
Àwọn ìran ọmọ Merari: Mahili, Libni ọmọ rẹ̀. Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀.
Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Mahili: Eleasari àti Kiṣi.
Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.
Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.
Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣerebiah wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ìran Mahili, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli, àti àwọn ọmọ Ṣerebiah àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìdínlógún.