Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Agriculture or Husbandry

132 ẹsẹ · 75 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

  2. Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

  3. Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.

  4. Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”

  5. Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Edeni láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá.

  6. Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.

  7. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi gégùn ún.”

  8. Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà.

  9. Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.)

  10. sá à wò ó, àwa ń yí ìtí ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìtí ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì dúró yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”

  11. “Bí ọkùnrin kan bá ń bọ́ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ lórí pápá tàbí nínú ọgbà àjàrà, tí ó sì jẹ́ kí ó lọ jẹ nínú oko ẹlòmíràn, a ó mú kí ó san ohun ti ẹran rẹ̀ jẹ padà pẹ̀lú èyí tí ó dára jù nínú oko tàbí nínú ọgbà rẹ̀ (ẹlòmíràn padà fún un).

  12. “Bí iná bá ṣẹ́ tí ó kán lu igbó tí ó sì jó àká ọkà tàbí gbogbo oko náà, ẹni tí iná ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ yóò san ohun tí iná ti ó ṣẹ́ jó padà.

  13. “Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrín yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé.

  14. “Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀.

  15. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni tálákà láàrín yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà àjàrà rẹ àti ọgbà olifi rẹ.

  16. Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”

  17. “ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀).

  18. Ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi gbin oko rẹ, ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ, tí ìwọ ó sì fi kó èso wọn jọ.

  19. “ ‘Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àjèjì àti ayálégbé.

  20. Ní gbogbo orílẹ̀-èdè ìní yín, ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà.

  21. “ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá tálákà, dé bi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó súnmọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà.

  22. Ẹni tí kò ní ẹni tó lè rà á padà fún un, tí òun fúnra rẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á.

  23. Kí ó mọ iye owó tí ó jẹ fún iye ọdún tí ó tà á, kí ó dá iye tí ó kù padà fún ẹni tí ó tà á fún, lẹ́yìn náà, ó lè padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

  24. Ṣùgbọ́n bí kò bá rí ọ̀nà àti san án padà fún un. Ohun tí ó tà wà ní ìkáwọ́ ẹni tí ó rà á títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ó dá a padà fún ẹni tí ó ni i ní ọdún ìdásílẹ̀, ẹni tí ó ni í tẹ́lẹ̀ lè tún padà gbà ohun ìní rẹ̀.

  25. Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso.