Skip to content

Boaz

24 ẹsẹ · 4 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Booz

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Boaz

  1. Naomi ní ìbátan kan láti ìdílé Elimeleki ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi.

  2. Rutu sì jáde lọ láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn. Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Boasi tí ó ti ìdílé Elimeleki wá ni ó lọ láìmọ̀-ọ́n-mọ̀.

  3. Nígbà náà ni Boasi dé láti Bẹtilẹhẹmu tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ.”

  4. Boasi sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?”

  5. Nígbà náà ni Boasi sọ fún Rutu pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣá ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi.

  6. Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí.

  7. Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Boasi sọ fún Rutu pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yìí kí o sì fi run wáìnì kíkan.” Òun sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Boasi sì fún un ní ọkà yíyan. Òun sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù.

  8. Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣá ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàrín oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́.

  9. Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, “Níbo ni ìwọ ti ṣá ọkà lónìí? Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́? Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ.” Rutu sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, “Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi ni mo ti ṣiṣẹ́ lónìí.”

  10. Rutu sì bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin Boasi ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà barle àti ti jéró. Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.

  11. Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí.

  12. Nígbà tí Boasi parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà tí wọ́n kójọ. Rutu yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

  13. Nígbà náà ni Boasi gòkè lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó sì jókòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó súnmọ́ Elimeleki jùlọ, arákùnrin tí Boasi ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Boasi pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jókòó.” Ó sì lọ jókòó.

  14. Nígbà náà ni Boasi sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Naomi àti lọ́wọ́ Rutu ará Moabu, ìwọ gbọdọ̀ fẹ́ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.”

  15. Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Boasi wí pé, “Ìwọ rà á fúnra rẹ̀,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

  16. Nígbà náà ni Boasi wí fún àwọn àgbàgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimeleki àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Maloni àti Kilioni lọ́wọ́ Naomi.

  17. Báyìí ni Boasi ṣe mú Rutu, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyún, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan.

  18. Salmoni ni baba Boasi, Boasi ni baba Obedi,

  19. Ó sì gbé àwọn ọ̀wọn náà ró ní ìloro tẹmpili, ó sì pe orúkọ ọ̀wọ́n tí ó wà ní gúúsù ní Jakini àti èyí tí ó wà ní àríwá ní Boasi.

  20. Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi,

  21. Boasi baba Obedi àti Obedi baba Jese.

  22. Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa, ọ̀kan sí gúúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúúsù, ó sọ ní Jakini àti èyí ti àríwá, ó sọ ní Boasi.

  23. Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese;

  24. tí í ṣe ọmọ Jese, tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi, tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,