Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Heir

39 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Abrahamu sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Isaaki.

  2. Ṣùgbọ́n kí Abrahamu tó kú, Abrahamu fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Isaaki ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà-oòrùn.

  3. Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrín yín. Wọn yóò sì di ohun ìní yín.

  4. Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín, wọ́n sì lè sọ wọ́n di ẹrú títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Israẹli kankan.

  5. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀.

  6. Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀.

  7. Tí kò bá ní arákùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀.

  8. Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ”

  9. Àwọn olórí ìdílé Gileadi, ọmọkùnrin Makiri ọmọ Manase tí ó wá láti ara ìdílé ìran Josẹfu wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mose àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Israẹli.

  10. Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Selofehadi arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.

  11. Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Israẹli mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbà á kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa.

  12. Nígbà tí ọdún ìdásílẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ baba ńlá wọn.”

  13. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mose pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìran Josẹfu ń sọ tọ̀nà.

  14. Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Selofehadi: wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.

  15. Kò sí ogún kan ní Israẹli tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Israẹli ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn pamọ́.

  16. Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Israẹli lè ní ìpín nínú ogún baba wọn.

  17. Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn.

  18. Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn.

  19. Ó ní láti fi ipò ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn fun un gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí i rẹ̀ nípa fífún un ní ìlọ́po ìpín gbogbo ohun tí ó ní. Ọmọ yẹn ni àmì àkọ́kọ́ agbára baba rẹ̀. Ẹ̀tọ́ àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀.

  20. Nísinsin yìí Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́: Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.

  21. Wọ́n sì lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni, àti àwọn olórí wí pé, “Olúwa pàṣẹ fún Mose láti fún wa ní ìní ní àárín àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa.

  22. Ìpín ilẹ̀ Manase sì jẹ́ ìsọ̀rí mẹ́wàá ní ẹ̀bá Gileadi àti Baṣani ìlà-oòrùn Jordani,

  23. nítorí tí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀yà Manase gba ìní ní àárín àwọn ọmọkùnrin. Ilẹ̀ Gileadi sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ọmọ Manase.

  24. Nígbà náà ni Boasi gòkè lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó sì jókòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó súnmọ́ Elimeleki jùlọ, arákùnrin tí Boasi ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Boasi pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jókòó.” Ó sì lọ jókòó.

  25. Boasi sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbàgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí ṣe bẹ́ẹ̀,