Skip to content

Zelophehad

9 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Zelophehad

  1. (Selofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).

  2. Ọmọbìnrin Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.

  3. “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ń sọ tọ̀nà. O gbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.

  4. Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Selofehadi arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.

  5. Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Selofehadi: wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.

  6. Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

  7. Nítorí pé a gbé Mahila, Tirsa, Hogla, Milka, àti Noa, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn.

  8. Nísinsin yìí Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́: Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.

  9. Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Selofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.