Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Obed

14 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Naomi.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Obedi. Òun sì ni baba Jese tí í ṣe baba Dafidi.

  2. Èyí ni ìran Peresi: Peresi ni baba Hesroni,

  3. Hesroni ni baba Ramu, Ramu ni baba Amminadabu

  4. Amminadabu ni baba Nahiṣoni, Nahiṣoni ni baba Salmoni,

  5. Salmoni ni baba Boasi, Boasi ni baba Obedi,

  6. Obedi ní baba Jese, Jese ni baba Dafidi.

  7. Boasi baba Obedi àti Obedi baba Jese.

  8. Sabadi ni baba Eflali, Eflali jẹ́ baba Obedi,

  9. Obedi sì ni baba Jehu, Jehu ni baba Asariah,

  10. Elieli, Obedi àti Jaasieli ará Mesoba.

  11. Àwọn ọmọ Ṣemaiah: Otni, Refaeli, Obedi àti Elsabadi; àwọn ìbátan rẹ̀ Elihu àti Samakiah jẹ́ ọkùnrin alágbára.

  12. Ní ọdún keje, Jehoiada fi agbára rẹ̀ hàn. O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún kan, Asariah ọmọ Jerohamu, Iṣmaeli ọmọ Jehohanani Asariah ọmọ Obedi, Maaseiah ọmọ Adaiah àti Elisafati ọmọ Sikri.

  13. Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese;

  14. tí í ṣe ọmọ Jese, tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi, tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,