Skip to content

Ruth

13 ẹsẹ · 3 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Ruth

  1. Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Moabu méjì, orúkọ ọ̀kan ń jẹ́ Oripa, èkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá,

  2. Wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì tún sọkún. Nígbà náà ní Oripa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rutu dì mọ́ ọn síbẹ̀.

  3. Ṣùgbọ́n Rutu dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí ìwọ bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ìwọ bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.

  4. Báyìí ni Naomi ṣe padà láti Moabu pẹ̀lú Rutu, ará Moabu ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹtilẹhẹmu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà barle.

  5. Rutu ará Moabu sì wí fún Naomi pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojúrere rẹ̀ pàdé.” Naomi sì sọ fún un pé, “Máa lọ, ọmọbìnrin mi.”

  6. Nígbà náà ni Boasi sọ fún Rutu pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣá ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi.

  7. Rutu, ará Moabu sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣá ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ”

  8. Naomi sì sọ fún Rutu, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”

  9. Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?” Rutu sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rutu, ìránṣẹ́bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.”

  10. Nígbà náà ni Boasi sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Naomi àti lọ́wọ́ Rutu ará Moabu, ìwọ gbọdọ̀ fẹ́ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.”

  11. Ní àfikún, mo ra Rutu ará Moabu opó Maloni padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrín àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”

  12. Báyìí ni Boasi ṣe mú Rutu, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyún, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan.

  13. Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese;