Skip to content

Joash

8 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Joash

  1. Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù Ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani.

  2. Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Lẹ́yìn tí wọn fi ara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.”

  3. Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Joaṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.”

  4. Ṣùgbọ́n Joaṣi bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Baali bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni olúwa rẹ̀ yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Baali bá ṣe Ọlọ́run nítòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.”

  5. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gideoni ọmọ Joaṣi ará Israẹli lọ: Ọlọ́run ti fi àwọn ará Midiani àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́.”

  6. Gideoni ọmọ Joaṣi gba ọ̀nà ìgòkè Heresi padà sẹ́yìn láti ojú ogun.

  7. Jerubbaali ọmọ Joaṣi padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀.

  8. Gideoni ọmọ Joaṣi kú ní ògbólógbòó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ofira ti àwọn ará Abieseri.