- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Offerings
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èso ilẹ̀ rẹ̀.
Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀,
Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀, ó sì ta ọrẹ ohun mímu sí orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú.
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti di líle, ó kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ó lọ.
“Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú ẹbọ sí òrìṣà yàtọ̀ sí Olúwa nìkan, ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun.
“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ìre oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ. “Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi.
Ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú agbo màlúù rẹ àti agbo àgùntàn rẹ. Jẹ́ kí wọn wà lọ́dọ̀ ìyá wọn fún ọjọ́ méje, kí ìwọ kí ó sì fi wọ́n fún mi ní ọjọ́ kẹjọ.
“Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí.
Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká.
Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n ọn sára Aaroni àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.
“Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́.)
Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Aaroni, ìwọ yóò si fí ì ni ẹbọ fífì níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.
“Ìwọ yóò sì ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́, àti ìtàn ẹbọ à gbé sọ sókè tí a fì, tí a sì gbé sọ sókè nínú àgbò ìyàsímímọ́ náà, àní nínú èyí tí í ṣe Aaroni àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀.
Èyí ni yóò sì máa ṣe ìpín ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à gbé sọ sókè ni ẹbọ tí yóò ṣì ṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli yóò máa ṣe sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.
“Ìwọ yóò sì mú àgbò fún ìyàsímímọ́, ìwọ yóò sì bọ ẹran rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan.
Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn ti àkọ́kọ́ rú ẹbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára olifi tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu.
Ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ni kí ìwọ kí ó pa rú ẹbọ ní àṣálẹ́ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa.
Aaroni yóò sì tún jó tùràrí nígbà tí ó bá tan fìtílà ní àṣálẹ́, bẹ́ẹ̀ ní tùràrí yóò máa jó títí láé níwájú Olúwa fún àwọn ìran tó ń bọ̀.
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mú àjèjì tùràrí wá sórí pẹpẹ yìí tàbí ẹbọ sísun kankan tàbí ọrẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ da ẹbọ ohun mímu sórí i rẹ̀.
Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa.
Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì ṣékélì lọ, àwọn tálákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì ṣékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún Olúwa láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.
Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa.
“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa
kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un.
Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájú Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í ṣe ọmọ Aaroni yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ká.