Skip to content

Place

19 verses

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Place

  1. Ṣo aṣọ títa náà sí ìsàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà Ibi Mímọ́ kúrò ní Ibi Mímọ́ Jùlọ.

  2. “Nígbàkígbà tí Aaroni bá wọ Ibi Mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Israẹli ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinnu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa.

  3. Aaroni gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́. A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ Ibi Mímọ́ níwájú Olúwa àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú.

  4. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọdọ̀ wọ̀ wọ́n nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ lọ tàbí nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ ní Ibi Mímọ́ kí wọn kí ó má ba à dẹ́ṣẹ̀, wọn a sì kú. “Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún Aaroni àti fún irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

  5. Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní Ibi Mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje.

  6. òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún Ibi Mímọ́. “Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.”

  7. Aṣọ híhun láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.”

  8. Nínú aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ibi mímọ́. Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  9. aṣọ híhun tí wọ́n ń wọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.

  10. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kankan, èyí tí wọ́n bá mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ètùtù ní Ibi Mímọ́, sísun ni kí ẹ sun ún.

  11. Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Kìlọ̀ fún Aaroni arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí Ibi Mímọ́ Jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má ba à kú nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú.

  12. “Báyìí ni Aaroni yóò ṣe máa wá sí Ibi Mímọ́ Jùlọ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun.

  13. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún Ibi Mímọ́ Jùlọ nítorí àìmọ́ àwọn ará Israẹli àti nítorí gbogbo ìrékọjá wọn àti ìṣọ̀tẹ̀ wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbogbo, bákan náà ni yóò sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tí ó wà láàrín wọn nínú àìmọ́ wọn.

  14. Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ láti ṣe ètùtù, títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnra rẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Israẹli.

  15. “Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti Ibi Mímọ́ Jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ, òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá.

  16. “Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí Ibi Mímọ́ Jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀.

  17. Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan, yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú, yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn.

  18. Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí Ibi Mímọ́ Jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà.

  19. Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́.