Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Offerings

433 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n òun, lẹ́yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run;

  2. láti ìgbà náà, ó retí títí a o fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.

  3. Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé.

  4. Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si Ibi Mímọ́ Jùlọ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ́yìn ibùdó.

  5. Nítorí náà Jesu pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ́yìn ibodè.

  6. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀.

  7. Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.

  8. Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo.