Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Miracles: Those who performed

5 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Those who performed

  1. Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.”

  2. Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láìṣiyèméjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú ohun tí a ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́, ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú Òkun,’ yóò sì rí bẹ́ẹ̀.

  3. Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.

  4. Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jesu, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jesu àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.

  5. Stefanu tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ àmì ńlá láàrín àwọn ènìyàn.