Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parables

452 ẹsẹ · 74 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti fi òróró yan ọba fún ara wọn. Wọ́n pe igi Olifi pé, ‘Wá ṣe ọba wa.’

  2. “Ṣùgbọ́n igi Olifi dá wọn lóhùn pé, ‘Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣe olórí àwọn igi?’

  3. “Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jẹ ọba ní orí wa.’

  4. “Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Kí èmi fi èso mi tí ó dára tí ó sì dùn sílẹ̀ láti wá ṣe olórí àwọn igi?’

  5. “Àwọn igi sì tún sọ fún àjàrà pé, ‘Wá, kí o ṣe ọba wa.’

  6. “Ṣùgbọ́n àjàrà dáhùn pé, ‘Ṣé kí èmi dẹ́kun àti máa so èso wáìnì mi èyí tí ó ń mú inú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn dùn láti máa ṣe olórí àwọn igi?’

  7. “Ní ìparí gbogbo àwọn igi lọ bá igi ẹ̀gún wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Wá kí ó ṣe ọba wa.’

  8. “Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Bí olóòtítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín. Ẹ sá àsálà sí abẹ́ ibòòji mi; ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi kedari àti ti Lebanoni run!’

  9. Olúwa sì rán Natani sí Dafidi òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan; ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ tálákà.

  10. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  11. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tálákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́, ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un.

  12. “Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀, láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá, o sì mú àgùntàn ọkùnrin tálákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá.”

  13. Ìbínú Dafidi sì ru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Natani pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú.

  14. Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rin mẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.”

  15. Ọba sì bi í léèrè pé, “Kín ni o ṣe ọ́?” Òun sì dáhùn wí pé, “Nítòótọ́ opó ni èmi ń ṣe, ọkọ mi sì kú.

  16. Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á.

  17. Sì wò ó, gbogbo ìdílé dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Fi ẹni tí ó pa arákùnrin rẹ fún wa, àwa ó sì pa á ní ipò ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ tí ó pa, àwa ó sì pa àrólé náà run pẹ̀lú.’ Wọn ó sì pa iná mi tí ó kù, wọn kì yóò sì fi orúkọ tàbí ẹni tí ó kú sílẹ̀ fún ọkọ mi ní ayé.”

  18. Ọba sì wí fún obìnrin náà pé, “Lọ sí ilé rẹ̀, èmi ó sì kìlọ̀ nítorí rẹ.”

  19. Obìnrin ará Tekoa náà sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lórí ìdílé baba mí; kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi.”

  20. Ọba sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ sí ọ, mú ẹni náà tọ̀ mí wá, òun kì yóò sì tọ́ ọ mọ́.”

  21. Ó sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe ìparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi!” Òun sì wí pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀.”

  22. Obìnrin náà sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi ọba.” Òun si wí pé, “Máa wí.”

  23. Ahijah sì gbá agbádá tuntun tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá.

  24. Nígbà náà ni ó sọ fún Jeroboamu pé, “Mú ọ̀nà mẹ́wàá fún ara rẹ, nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Wò ó, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Solomoni, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.

  25. Ṣùgbọ́n nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, òun yóò ní ẹ̀yà kan.