Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parables: Of a vine of Egypt

9 ẹsẹ · 74 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Of a vine of Egypt

  1. Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti; ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.

  2. Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un, ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀ ó sì kún ilẹ̀ náà.

  3. A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.

  4. O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun, ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.

  5. Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?

  6. Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́ àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.

  7. Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára! Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó! Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,

  8. gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn, àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.

  9. A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún; ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.