Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parables: Lost sheep

5 ẹsẹ · 74 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Lost sheep

  1. Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé,

  2. “Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún yokù sílẹ̀ ni ijù tí kì yóò sì tọ ipasẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i?

  3. Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀.

  4. Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’

  5. Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòtítọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.