Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parables

452 ẹsẹ · 74 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀?

  2. Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.

  3. Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili, bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini; ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde, ọ̀gọ ni a sì lu kummini.

  4. A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà; bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé. Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀, àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.

  5. Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá, oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.

  6. “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’

  7. Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu.

  8. Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí. Èmi kì yóò dáríjì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti máa pa wọ́n run.’ ”

  9. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:

  10. “Ọmọ ènìyàn, báwo ni igi àjàrà ṣe dára ju igi mìíràn lọ tàbí jù ẹ̀ka àjàrà tó wà láàrín igi yòókù nínú igbó?

  11. Ǹjẹ́ a wa lè mú igi lára rẹ̀ ṣe nǹkan tí ó wúlò bí? Tàbí kí ènìyàn fi ṣe èèkàn tí yóò fi nǹkan kọ́?

  12. Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárín rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́?

  13. Tí kò bá wúlò fún nǹkan kan nígbà tó wà lódidi, báwo ni yóò ṣe wá wúlò nígbà tí iná ti jó o, tó sì dúdú nítorí èéfín?

  14. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bí mo ṣe sọ igi àjàrà tó wà láàrín àwọn igi inú igbó yòókù di igi ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe ṣe gbogbo ènìyàn tó ń gbé Jerusalẹmu.

  15. Èmi yóò dojúkọ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan, síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn. Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  16. Èmi yóò sọ ilé náà di ahoro nítorí ìwà àìṣòótọ́ wọn, ni Olúwa Olódùmarè wí.”

  17. “ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò.

  18. Ó dàgbà, ó sì di àjàrà tó kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú sí i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó di àjàrà, ó sì mu ẹ̀ka àti ewé jáde.

  19. “ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó le fún un ni omi.

  20. Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sì so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’

  21. “Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyí, yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì nígbà agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòǹgbò rẹ̀ tu.

  22. Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátápátá nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn bá kọlù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”

  23. “Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli

  24. wí pé: “ ‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù? Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

  25. Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára, ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.