Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions

636 ẹsẹ · 252 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀,”

  2. “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

  3. Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”

  4. Wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

  5. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.”

  6. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ ṣe baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà.

  7. Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.”

  8. Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà? Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.”

  9. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́; À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”

  10. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ. Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.”

  11. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”

  12. kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”

  13. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.”

  14. Nítorí ó wí fún Mose pé, “Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.”

  15. Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.”

  16. Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ”

  17. Yóò sì ṣe, “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”

  18. Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé: “Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun, apá kan ni ó gbàlà.

  19. Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”

  20. Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sodomu, a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.”

  21. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”

  22. Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.”

  23. Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?’ ” (èyí ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀),

  24. “tàbí, ‘Ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?’ ” (èyí ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá).

  25. Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù pé: