Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions

636 ẹsẹ · 252 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé.

  2. Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà, nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí Olúwa ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí Olúwa yóò pè.

  3. “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?

  4. Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè, ibùgbé àwọn òrìṣà yín, àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ, èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.

  5. Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,” ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.

  6. “Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró, Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya, Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè, Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,

  7. kí wọn le jogún ìyókù Edomu àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,” ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.

  8. “Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata, bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda, nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà láéláé.”

  9. “Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye, kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi. Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.

  10. “Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga, ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

  11. “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

  12. Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín.

  13. Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

  14. Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.

  15. Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa.

  16. “Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu, wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀.

  17. “Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi, àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn, àwọn àgùntàn a sì túká: èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké.

  18. “Èmí ti fẹ́ ẹ yín,” ni Olúwa wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ wa?’ “Esau kì í ha ṣe arákùnrin Jakọbu bí?” ni Olúwa wí. “Síbẹ̀ èmi fẹ́ràn Jakọbu,

  19. ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra, mo ti sọ àwọn òkè ńlá rẹ̀ di aṣálẹ̀, mo sì fi ìní rẹ̀ fún àwọn akátá aginjù.”

  20. “Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ́ mi, yóò tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni Olúwa, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹmpili rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  21. Òun yóò sì pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sì ti àwọn baba wọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò wá, èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà gégùn.”

  22. “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa”).

  23. “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea, ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda; nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde, ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’ ”

  24. ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé, “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”

  25. “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá, Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”