- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1406–1380 BC
Conquest of Canaan
Joshua leads Israel across the Jordan into the promised land, defeating the Canaanite kingdoms one by one.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Joṣua 19:31nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé.
- Joṣua 19:32nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Ìpín kẹfà jáde fún Naftali, agbo ilé ní agbo ilé,
- Joṣua 19:33nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
ààlà wọn lọ láti Helefi àti igi ńlá ní Saananimu nímù; kọjá lọ sí Adami Nekebu àti Jabneeli dé Lakkumu, ó sì pín ní Jordani.
- Joṣua 19:34nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Asnoti-Tabori ó sì jáde ní Hukoki. Ó sì dé Sebuluni, ní ìhà gúúsù Aṣeri ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Juda ní Jordani ní ìhà ìlà-oòrùn.
- Joṣua 19:35nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Àwọn ìlú olódi sì Siddimu, Seri, Hamati, Rakàti, Kinnereti,
- Joṣua 19:36nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Adama, Rama Hasori,
- Joṣua 19:37nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Kedeṣi, Edrei, Eni-Aṣọri,
- Joṣua 19:38nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Ironi, Migdali-Eli, Horemu, Beti-Anati àti Beti-Ṣemeṣi. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàndínlógún àti ìletò wọn.
- Joṣua 19:39nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Naftali, ní agbo ilé sí agbo ilé.
- Joṣua 19:40nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Ìbò kéje jáde fún ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé ní agbo ilé.
- Joṣua 19:41nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ ìní wọn nìwọ̀nyí: Sora, Eṣtaoli, Iri-Ṣemesi,
- Joṣua 19:42nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Ṣaalabini, Aijaloni, Itila,
- Joṣua 19:43nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Eloni, Timna, Ekroni,
- Joṣua 19:44nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Elteke, Gibetoni, Baalati,
- Joṣua 19:45nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Jehudu, Bene-Beraki, Gati-Rimoni,
- Joṣua 19:46nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Me Jakoni àti Rakkoni, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Joppa.
- Joṣua 19:47nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
(Ṣùgbọ́n àwọn ará Dani ní ìṣòro láti gba ilẹ̀ ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Leṣemu, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Leṣemu, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dani orúkọ baba ńlá wọn).
- Joṣua 19:48nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Àwọn ìlú wọ́n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé agbo ilé.
- Joṣua 19:49nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Israẹli fún Joṣua ọmọ Nuni ní ìní ní àárín wọn,
- Joṣua 19:50nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
bí Olúwa ti pàṣẹ, wọ́n fún un ni ìlú tí ó béèrè fún, Timnati Serah ní ìlú òkè Efraimu. Ó sì kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé ibẹ̀.
- Joṣua 19:51nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Israẹli fi ìbò pín ní Ṣilo ní iwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.
- Joṣua 20:1nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé,
- Joṣua 20:2nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn yan àwọn ìlú ààbò, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ láti ẹnu Mose,
- Joṣua 20:3nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
kí ẹni tí ó bá ṣèèṣì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa.
- Joṣua 20:4nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbàgbà ìlú náà. Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàrín wọn.