Fò sí àkóónú

circa 1406–1380 BC

Conquest of Canaan

Joshua leads Israel across the Jordan into the promised land, defeating the Canaanite kingdoms one by one.

658 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Joṣua 18:9nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Ṣilo.

  2. Joṣua 18:10nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú Olúwa, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.

  3. Joṣua 18:11nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Benjamini, ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàrín ti ẹ̀yà Juda àti Josẹfu.

  4. Joṣua 18:12nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jordani, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jeriko ní ìhà àríwá, ó sì forí lé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí aginjù Beti-Afeni.

  5. Joṣua 18:13nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúúsù ní ọ̀nà Lusi (tí í ṣe Beteli) ó sì dé Atarotu-Addari, ní orí òkè tí ó wà ní gúúsù Beti-Horoni.

  6. Joṣua 18:14nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Láti òkè tí ó kọjú sí Beti-Horoni ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Baali (tí í ṣe Kiriati-Jearimu), ìlú àwọn ènìyàn Juda. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.

  7. Joṣua 18:15nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jearimu ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nefitoa.

  8. Joṣua 18:16nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí àfonífojì Beni-Hinnomu, àríwá àfonífojì Refaimu. O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí àfonífojì Hinnomu sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jebusi, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-Rogeli.

  9. Joṣua 18:17nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni-Ṣemeṣi, ó tẹ̀síwájú dé Geliloti tí ó kọjú sí òkè Adummimu, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Òkúta Bohani ọmọ Reubeni.

  10. Joṣua 18:18nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Ó tẹ̀síwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Araba, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù.

  11. Joṣua 18:19nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Hogla, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jordani ní gúúsù. Èyí ni ààlà ti gúúsù.

  12. Joṣua 18:20nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Odò Jordani sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn. Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sàmì sí ìní àwọn ìdílé Benjamini ní gbogbo àwọn àyíká wọn.

  13. Joṣua 18:21nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yà Benjamini ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí: Jeriko, Beti-Hogla, Emeki-Keṣiṣi,

  14. Joṣua 18:22nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Beti-Araba, Semaraimu, Beteli,

  15. Joṣua 18:23nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Affimu, Para, Ofira

  16. Joṣua 18:24nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Kefari, Ammoni, Ofini àti Geba; àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

  17. Joṣua 18:25nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Gibeoni, Rama, Beeroti,

  18. Joṣua 18:26nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Mispa, Kefira, Mosa,

  19. Joṣua 18:27nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Rekemu, Irpeeli, Tarala,

  20. Joṣua 18:28nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Ṣela, Haelefi, ìlú Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu), Gibeah àti Kiriati, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn. Èyí ni ìní Benjamini fún ìdílé rẹ̀.

  21. Joṣua 19:1nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Kèké kejì jáde fún ẹ̀yà Simeoni, ní agbo ilé, ní agbo ilé. Ìní wọn sì wà ní àárín ilẹ̀ Juda.

  22. Joṣua 19:2nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Lára ìpín wọn ní: Beerṣeba (tàbí Ṣeba), Molada,

  23. Joṣua 19:3nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Hasari-Ṣuali, Bala, Esemu,

  24. Joṣua 19:4nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Eltoladi, Betuli, Horma,

  25. Joṣua 19:5nǹkan bí 1443 ṣáájú Kristi

    Siklagi, Beti-Markaboti, Hasari Susa,