Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Kọrinti 16:5nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrín Makedonia: nítorí èmi yóò kọjá láàrín Makedonia.

  2. 1 Kọrinti 16:6nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbí kí n tilẹ̀ lo àkókò òtútù, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ.

  3. 1 Kọrinti 16:7nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́.

  4. 1 Kọrinti 16:8nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Efesu títí dí Pentikosti.

  5. 1 Kọrinti 16:9nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ.

  6. 1 Kọrinti 16:10nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù, nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe.

  7. 1 Kọrinti 16:11nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.

  8. 1 Kọrinti 16:12nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.

  9. 1 Kọrinti 16:13nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára.

  10. 1 Kọrinti 16:14nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́.

  11. 1 Kọrinti 16:15nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́.

  12. 1 Kọrinti 16:16nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá.

  13. 1 Kọrinti 16:17nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Mo láyọ̀ fún wíwá Stefana àti Fortunatu àti Akaiku, nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fi kún un.

  14. 1 Kọrinti 16:18nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba irú àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.

  15. 1 Kọrinti 16:19nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ìjọ ni Asia kí í yín. Akuila àti Priskilla kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.

  16. 1 Kọrinti 16:20nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

  17. 1 Kọrinti 16:21nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ìkíni ti èmi Paulu, láti ọwọ́ èmi tìkára mi wá.

  18. 1 Kọrinti 16:22nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kristi Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!

  19. 1 Kọrinti 16:23nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!

  20. 1 Kọrinti 16:24nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jesu. Àmín.

  21. 2 Kọrinti 1:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Paulu aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Timotiu arákùnrin wá, Sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọrinti pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Akaia:

  22. 2 Kọrinti 1:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa.

  23. 2 Kọrinti 1:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.

  24. 2 Kọrinti 1:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

  25. 2 Kọrinti 1:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi.