Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Kọrinti 15:38nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irúgbìn ara tirẹ̀.

  2. 1 Kọrinti 15:39nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ.

  3. 1 Kọrinti 15:40nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ, ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀.

  4. 1 Kọrinti 15:41nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀tọ̀ ni ògo ti oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.

  5. 1 Kọrinti 15:42nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a sí jì í dìde ni àìdíbàjẹ́.

  6. 1 Kọrinti 15:43nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì jí í dìde ní agbára.

  7. 1 Kọrinti 15:44nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    A gbìn ín ni, ara ẹran a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí. Bí ara ẹran bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ.

  8. 1 Kọrinti 15:45nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Adamu ọkùnrin ìṣáájú, alààyè ọkàn ni a dá a”; Adamu ìkẹyìn ẹ̀mí ìsọnidààyè.

  9. 1 Kọrinti 15:46nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáájú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ara ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí.

  10. 1 Kọrinti 15:47nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni.

  11. 1 Kọrinti 15:48nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.

  12. 1 Kọrinti 15:49nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Bí àwa ti rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àwòrán ẹni ti ọ̀run.

  13. 1 Kọrinti 15:50nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́.

  14. 1 Kọrinti 15:51nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Kíyèsi í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín, gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà.

  15. 1 Kọrinti 15:52nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà.

  16. 1 Kọrinti 15:53nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀.

  17. 1 Kọrinti 15:54nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní ìṣẹ́gun.”

  18. 1 Kọrinti 15:55nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    “Ikú, oró rẹ dà? Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?”

  19. 1 Kọrinti 15:56nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin.

  20. 1 Kọrinti 15:57nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi!

  21. 1 Kọrinti 15:58nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, ní ìwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.

  22. 1 Kọrinti 16:1nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe.

  23. 1 Kọrinti 16:2nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé.

  24. 1 Kọrinti 16:3nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jerusalẹmu.

  25. 1 Kọrinti 16:4nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.