Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jakọbu 1:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Jakọbu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa, Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káàkiri, orílẹ̀-èdè: Àlàáfíà.

  2. Jakọbu 1:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀;

  3. Jakọbu 1:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù.

  4. Jakọbu 1:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun.

  5. Jakọbu 1:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un.

  6. Jakọbu 1:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.

  7. Jakọbu 1:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa;

  8. Jakọbu 1:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìlèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo.

  9. Jakọbu 1:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga.

  10. Jakọbu 1:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ.

  11. Jakọbu 1:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru gbígbóná yóò gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànù, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.

  12. Jakọbu 1:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdánwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ.

  13. Jakọbu 1:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Kí ẹnikẹ́ni tí a dánwò kí ó má ṣe wí pé, “Láti ọwọ́ Ọlọ́run ni a ti dán mi wò.” Nítorí a kò lè fi búburú dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò;

  14. Jakọbu 1:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dánwò nígbà tí a bá fi ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ.

  15. Jakọbu 1:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nígbà tí ó bá lóyún a bí ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá dàgbà tán, a bí ikú.

  16. Jakọbu 1:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́.

  17. Jakọbu 1:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.

  18. Jakọbu 1:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá.

  19. Jakọbu 1:19nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú;

  20. Jakọbu 1:20nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́.

  21. Jakọbu 1:21nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.

  22. Jakọbu 1:22nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ.

  23. Jakọbu 1:23nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí

  24. Jakọbu 1:24nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí.

  25. Jakọbu 1:25nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.