- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Efesu 1:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:
- Efesu 1:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa.
- Efesu 1:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi.
- Efesu 1:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́
- Efesu 1:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
ẹni tí ò ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀,
- Efesu 1:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí ò ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀.
- Efesu 1:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run
- Efesu 1:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye,
- Efesu 1:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi,
- Efesu 1:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.
- Efesu 1:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀,
- Efesu 1:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi.
- Efesu 1:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀,
- Efesu 1:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.
- Efesu 1:15nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
- Efesu 1:16nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi.
- Efesu 1:17nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i.
- Efesu 1:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́,
- Efesu 1:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀,
- Efesu 1:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run.
- Efesu 1:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.
- Efesu 1:22nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ,
- Efesu 1:23nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.
- Efesu 2:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín,
- Efesu 2:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí, àní bí ìlànà ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni ìsinsin yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.