Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 3 Johanu 1:1nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Alàgbà, Sì Gaiusi, olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ nínú òtítọ́.

  2. 3 Johanu 1:2nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ.

  3. 3 Johanu 1:3nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí mo yọ̀ gidigidi, nígbà tí àwọn arákùnrin dé tí wọn sì jẹ́rìí sí ìwà òtítọ́ inú rẹ̀, àní bí ìwọ tí ń rìn nínú òtítọ́.

  4. 3 Johanu 1:4nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Èmi ni ayọ̀ tí ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.

  5. 3 Johanu 1:5nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò.

  6. 3 Johanu 1:6nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ, bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run.

  7. 3 Johanu 1:7nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà.

  8. 3 Johanu 1:8nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.

  9. 3 Johanu 1:9nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Èmi kọ̀wé sí ìjọ ṣùgbọ́n Diotirefe, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá.

  10. 3 Johanu 1:10nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà bí mo bá dé, èmi yóò mú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe wá sì ìrántí rẹ, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ búburú àti ìsọkúsọ sí wa, èyí kò sì tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, síbẹ̀ òun fúnra rẹ̀ kọ̀ láti gba àwọn ará, àwọn tí ó sì ń fẹ́ gbà wọ́n, ó ń dá wọn lẹ́kun, ó sì ń lé wọn kúrò nínú ìjọ.

  11. 3 Johanu 1:11nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Olùfẹ́, má ṣe ṣe àfarawé ohun tí í ṣe ibi bí kò ṣe ohun tí ṣe rere. Ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti Ọlọ́run ni; ẹni tí ó ba ń ṣe búburú kò rí Ọlọ́run.

  12. 3 Johanu 1:12nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Demetriusi ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn àti ní ti òtítọ́ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú; nítòótọ́, àwa pẹ̀lú sì gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́; ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí wa.

  13. 3 Johanu 1:13nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Èmí ní ohun púpọ̀ láti kọ sínú ìwé sí ọ, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ fi kálàmù àti tawada kọ wọ́n sínú ìwé.

  14. 3 Johanu 1:14nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Mo ni ìrètí láti rí ọ láìpẹ́, tí àwa yóò sì sọ̀rọ̀ lójúkojú.