Skip to content

Asia

18 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Achaia

39.2300, 32.7300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Asia

  1. Àwọn ará Partia, àti Media, àti Elamu; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamia, Judea, àti Kappadokia, Pọntu àti Asia.

  2. Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń ṣe ara Sinagọgu, tí a ń pè ní Libataini. Àwọn Júù Kirene àti ti Alekisandiria àti ti Kilikia, àti ti Asia wá, wọ́n ń bá Stefanu jiyàn,

  3. Wọ́n sì la agbègbè Frigia já, àti Galatia, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Asia.

  4. Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki.

  5. Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia.

  6. Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.

  7. Kì í sì ṣe pé kìkì iṣẹ́ ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí asán; ṣùgbọ́n tẹmpili Artemisi òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọláńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Asia àti gbogbo ayé ń bọ.”

  8. Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti.

  9. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Asia, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà.

  10. Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un.

  11. Nínú ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mí nínú ìyẹ̀wù tẹmpili, bí mo ti ń parí ètò ìwẹ̀nù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ní àárín àwùjọ ènìyàn, tàbí pẹ̀lú ariwo.

  12. Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa.

  13. Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń péjọpọ̀ ní ilé wọn. Ẹ kí Epenetu ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di ti Kristi ní orílẹ̀-èdè Asia.

  14. Àwọn ìjọ ni Asia kí í yín. Akuila àti Priskilla kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.

  15. Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́.

  16. Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Asia ti fi mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Figeliu àti Hamogene gbé wà.

  17. Peteru, aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, tiwọn tú káàkiri sí Pọntu, Galatia, Kappadokia, Asia, àti Bitinia,

  18. Johanu, Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia: Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀;