- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Timotiu 1:1nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Paulu, aposteli Kristi Jesu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa, àti Jesu Kristi ìrètí wa,
- 1 Timotiu 1:2nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Sí Timotiu ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi Olúwa wa.
- 1 Timotiu 1:3nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Bí mo ṣe rọ̀ yìn nígbà tí mò ń lọ sí Makedonia, ẹ dúró ní Efesu, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́
- 1 Timotiu 1:4nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn asán, àti ìtàn ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́.
- 1 Timotiu 1:5nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn.
- 1 Timotiu 1:6nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápá kan sí ọ̀rọ̀ asán.
- 1 Timotiu 1:7nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.
- 1 Timotiu 1:8nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára.
- 1 Timotiu 1:9nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn,
- 1 Timotiu 1:10nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.
- 1 Timotiu 1:11nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.
- 1 Timotiu 1:12nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ó fún mi ní agbára, àní Kristi Jesu Olúwa wa, nítorí tí ó kà mí sí olóòtítọ́ ní yíyànmí sí iṣẹ́ rẹ̀.
- 1 Timotiu 1:13nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn, ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́.
- 1 Timotiu 1:14nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kristi Jesu.
- 1 Timotiu 1:15nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jesu Kristi wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ.
- 1 Timotiu 1:16nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni kí Jesu Kristi fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn.
- 1 Timotiu 1:17nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.
- 1 Timotiu 1:18nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Àṣẹ yìí ni mo pa fún ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tó ó ti ṣáájú nípa rẹ̀, pé nípasẹ̀ wọ́n kí ìwọ lè máa ja ìjà rere;
- 1 Timotiu 1:19nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
máa ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere. Èyí ti àwọn mìíràn ti mú kúrò lọ́dọ̀ wọn tí wọ́n sì rí ọkàn ìgbàgbọ́ wọn.
- 1 Timotiu 1:20nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Aleksanderu wà; àwọn tí mo ti fi lé Satani lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọ́n má sọ̀rọ̀-òdì mọ́.
- 1 Timotiu 2:1nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn.
- 1 Timotiu 2:2nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́.
- 1 Timotiu 2:3nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa;
- 1 Timotiu 2:4nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.
- 1 Timotiu 2:5nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi
Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà.