Laodicea
A tún mọ̀ ọ́n sí: Laodiceans
37.7600, 29.0600 Wo lórí Google Maps
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Laodicea
Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodikea àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí.
Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodikea, àti àwọn tí ó wà ní Hirapoli.
Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ní Laodikea, àti Nimpa, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.
Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárín yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodikea; ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodikea wá.
Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.”
“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.