Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alpha
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé, tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe? Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.”
“Ohun tí Olúwa wí nìyìí ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
“Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu Israẹli ẹni tí mo pè. Èmi ni ẹni náà; Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
“Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”
Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.”
Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.
Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.