- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Kolose 1:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa,
- Kolose 1:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose: Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.
- Kolose 1:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nígbàkígbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi.
- Kolose 1:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
- Kolose 1:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà,
- Kolose 1:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.
- Kolose 1:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa.
- Kolose 1:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.
- Kolose 1:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí.
- Kolose 1:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run,
- Kolose 1:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.
- Kolose 1:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀.
- Kolose 1:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn.
- Kolose 1:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
- Kolose 1:15nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.
- Kolose 1:16nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un.
- Kolose 1:17nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan.
- Kolose 1:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun.
- Kolose 1:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀.
- Kolose 1:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.
- Kolose 1:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín.
- Kolose 1:22nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi,
- Kolose 1:23nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìyìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún.
- Kolose 1:24nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ.
- Kolose 1:25nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fi fún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ.