- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Filemoni 1:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa, Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa,
- Filemoni 1:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:
- Filemoni 1:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Oore-ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.
- Filemoni 1:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,
- Filemoni 1:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́.
- Filemoni 1:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá.
- Filemoni 1:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára.
- Filemoni 1:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú Kristi mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ,
- Filemoni 1:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi.
- Filemoni 1:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè.
- Filemoni 1:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.
- Filemoni 1:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ.
- Filemoni 1:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìyìnrere
- Filemoni 1:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe.
- Filemoni 1:15nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé.
- Filemoni 1:16nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.
- Filemoni 1:17nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí.
- Filemoni 1:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn.
- Filemoni 1:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ.
- Filemoni 1:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Èmi ń fẹ́ arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Kristi.
- Filemoni 1:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́rọ̀, ni mo fi kọ ìwé yìí ránṣẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò ṣe ju bí mo ti béèrè lọ.
- Filemoni 1:22nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Ó ku ohun kan, ṣe ìtọ́jú iyàrá àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.
- Filemoni 1:23nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Epafira, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kristi Jesu kí ọ.
- Filemoni 1:24nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Marku kí ọ pẹ̀lú Aristarku, Dema àti Luku, àwọn alábáṣiṣẹ́ mi.
- Filemoni 1:25nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi
Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.