Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kọrinti 1:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́.

  2. 2 Kọrinti 1:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.

  3. 2 Kọrinti 1:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́.

  4. 2 Kọrinti 1:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde.

  5. 2 Kọrinti 1:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀,

  6. 2 Kọrinti 1:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fi àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere tí a rí gbà nípa ìdáhùn sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

  7. 2 Kọrinti 1:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí ní ìṣògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú si jẹ́rìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ti ara ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

  8. 2 Kọrinti 1:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí eyín kò lè kà àti ni mòye rẹ̀ sí yín. Mo sì tún ní ìrètí wí pé.

  9. 2 Kọrinti 1:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apá kan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jesu Olúwa.

  10. 2 Kọrinti 1:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnu láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jẹ àǹfààní ìgbà méjì.

  11. 2 Kọrinti 1:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea.

  12. 2 Kọrinti 1:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbèrò bẹ́ẹ̀, èmi ha ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?

  13. 2 Kọrinti 1:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòtítọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́.

  14. 2 Kọrinti 1:19nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàrín yín nípasẹ̀ èmí àti Silfanu àti Timotiu, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní.

  15. 2 Kọrinti 1:20nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kristi. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípasẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run.

  16. 2 Kọrinti 1:21nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọlọ́run ni ó fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kristi, Òun ni ó ti fi àmì òróró yàn wá,

  17. 2 Kọrinti 1:22nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.

  18. 2 Kọrinti 1:23nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àti dá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọrinti.

  19. 2 Kọrinti 1:24nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n àwa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró ṣinṣin.

  20. 2 Kọrinti 2:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà mo tí pinnu nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fi ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá.

  21. 2 Kọrinti 2:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́?

  22. 2 Kọrinti 2:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀, nítorí tí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi.

  23. 2 Kọrinti 2:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.

  24. 2 Kọrinti 2:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù.

  25. 2 Kọrinti 2:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un.