Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kọrinti 3:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkígbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn.

  2. 2 Kọrinti 3:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò.

  3. 2 Kọrinti 3:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà.

  4. 2 Kọrinti 3:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.

  5. 2 Kọrinti 4:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara,

  6. 2 Kọrinti 4:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run.

  7. 2 Kọrinti 4:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n báyìí, bí ìyìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé.

  8. 2 Kọrinti 4:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìyìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.

  9. 2 Kọrinti 4:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu.

  10. 2 Kọrinti 4:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.

  11. 2 Kọrinti 4:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá.

  12. 2 Kọrinti 4:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù.

  13. 2 Kọrinti 4:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run.

  14. 2 Kọrinti 4:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa.

  15. 2 Kọrinti 4:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú.

  16. 2 Kọrinti 4:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.

  17. 2 Kọrinti 4:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ pé, “Èmi gbàgbọ́, nítorí náà ni èmi ṣe sọ,” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ.

  18. 2 Kọrinti 4:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jesu Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jesu, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín,

  19. 2 Kọrinti 4:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.

  20. 2 Kọrinti 4:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́.

  21. 2 Kọrinti 4:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa.

  22. 2 Kọrinti 4:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.

  23. 2 Kọrinti 5:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.

  24. 2 Kọrinti 5:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá.

  25. 2 Kọrinti 5:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò.