Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kọrinti 5:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì.

  2. 2 Kọrinti 5:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèsè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.

  3. 2 Kọrinti 5:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.

  4. 2 Kọrinti 5:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí.

  5. 2 Kọrinti 5:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa.

  6. 2 Kọrinti 5:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

  7. 2 Kọrinti 5:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú.

  8. 2 Kọrinti 5:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú.

  9. 2 Kọrinti 5:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn.

  10. 2 Kọrinti 5:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni.

  11. 2 Kọrinti 5:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú.

  12. 2 Kọrinti 5:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

  13. 2 Kọrinti 5:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́.

  14. 2 Kọrinti 5:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé.

  15. 2 Kọrinti 5:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa.

  16. 2 Kọrinti 5:19nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́.

  17. 2 Kọrinti 5:20nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà.”

  18. 2 Kọrinti 5:21nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí, kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.

  19. 2 Kọrinti 6:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán.

  20. 2 Kọrinti 6:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí o wí pé, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ, àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.” Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.

  21. 2 Kọrinti 6:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀-òdì sí.

  22. 2 Kọrinti 6:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà,

  23. 2 Kọrinti 6:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀.

  24. 2 Kọrinti 6:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.

  25. 2 Kọrinti 6:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì.