- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Juda 1:9nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n Mikaeli, olórí àwọn angẹli, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítorí òkú Mose, kò sọ ọ̀rọ̀-òdì sí i; ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.”
- Juda 1:10nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀-òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa èrò ara ni, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.
- Juda 1:11nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora.
- Juda 1:12nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àsè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùṣọ́-àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọ́n tú tigbòǹgbò tigbòǹgbò.
- Juda 1:13nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi Òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde; alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé.
- Juda 1:14nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Enoku, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Adamu, sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn pé, “Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
- Juda 1:15nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i.”
- Juda 1:16nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nípa ara wọn, wọ́n sì ń ṣátá àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn.
- Juda 1:17nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ṣáájú láti ọwọ́ àwọn aposteli Olúwa wa Jesu Kristi.
- Juda 1:18nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.”
- Juda 1:19nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni ti ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.
- Juda 1:20nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́.
- Juda 1:21nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń retí àánú Olúwa wa Jesu Kristi tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun.
- Juda 1:22nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ẹ máa ṣàánú fún àwọn tí ń ṣe iyèméjì.
- Juda 1:23nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná; kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èérí.
- Juda 1:24nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọ̀sẹ̀, tí o sì lè mú yín wá síwájú ògo rẹ̀ láìlábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́—
- Juda 1:25nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
tí Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọláńlá, ìjọba àti agbára, nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, kí gbogbo ayé tó wà, nísinsin yìí àti títí láéláé! Àmín.