Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kọrinti 6:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́,

  2. 2 Kọrinti 6:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá,

  3. 2 Kọrinti 6:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.

  4. 2 Kọrinti 6:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ará Kọrinti, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa páyà sí yín.

  5. 2 Kọrinti 6:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àwa kò fa ìfẹ́ wa sẹ́yìn fún yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fa ìfẹ́ yín sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wa.

  6. 2 Kọrinti 6:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé, ẹ̀yin náà ẹ ṣí ọkàn yín páyà pẹ̀lú.

  7. 2 Kọrinti 6:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn?

  8. 2 Kọrinti 6:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?

  9. 2 Kọrinti 6:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé: “Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàrín wọn, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”

  10. 2 Kọrinti 6:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, “Ẹ jáde kúrò láàrín wọn, kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀, ni Olúwa wí. Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́; Èmi ó sì gbà yín.”

  11. 2 Kọrinti 6:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àti, “Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

  12. 2 Kọrinti 7:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  13. 2 Kọrinti 7:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ.

  14. 2 Kọrinti 7:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè.

  15. 2 Kọrinti 7:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.

  16. 2 Kọrinti 7:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú.

  17. 2 Kọrinti 7:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé,

  18. 2 Kọrinti 7:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.

  19. 2 Kọrinti 7:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀.

  20. 2 Kọrinti 7:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun.

  21. 2 Kọrinti 7:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá, ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú.

  22. 2 Kọrinti 7:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ń kọ́, ìbànújẹ́ ń kọ́, ìpayà ń kọ́, ìfojúṣọ́nà ń kọ́, ìtara ń kọ́, ìjẹ́ni-níyà ń kọ́. Nínú ohun àmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà.

  23. 2 Kọrinti 7:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run.

  24. 2 Kọrinti 7:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, a tí fi ìtùnú yín tù wá nínú. Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Titu ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára.

  25. 2 Kọrinti 7:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójútì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Titu sì jásí òtítọ́.