- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Kọrinti 14:28nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.
- 1 Kọrinti 14:29nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ.
- 1 Kọrinti 14:30nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Bí a bá sì fi ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́.
- 1 Kọrinti 14:31nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú.
- 1 Kọrinti 14:32nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì.
- 1 Kọrinti 14:33nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ìjọ ènìyàn mímọ́.
- 1 Kọrinti 14:34nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ìjọ, nítorí a kò fi fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn wà lábẹ́ ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí òfin pẹ̀lú ti wí.
- 1 Kọrinti 14:35nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn béèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.
- 1 Kọrinti 14:36nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Kín ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tàbí ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá?
- 1 Kọrinti 14:37nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tàbí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkan wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé òfin Olúwa ni wọ́n.
- 1 Kọrinti 14:38nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá fi ojú fo èyí dá, òun fúnra rẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.
- 1 Kọrinti 14:39nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà ará, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dánilẹ́kun láti fi èdè fọ̀.
- 1 Kọrinti 14:40nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.
- 1 Kọrinti 15:1nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìyìnrere náà dí mí mọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró.
- 1 Kọrinti 15:2nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nípasẹ̀ ìyìnrere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹ̀yin kàn gbàgbọ́ lásán.
- 1 Kọrinti 15:3nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti fi lé e yín lọ́wọ́, bí Kristi ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí.
- 1 Kọrinti 15:4nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí wí;
- 1 Kọrinti 15:5nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
àti pé ó farahàn Peteru, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá.
- 1 Kọrinti 15:6nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fi di ìsinsin yìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn.
- 1 Kọrinti 15:7nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jakọbu; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn aposteli.
- 1 Kọrinti 15:8nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Àti níkẹyìn gbogbo wọn ó farahàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀.
- 1 Kọrinti 15:9nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn aposteli, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní aposteli, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run.
- 1 Kọrinti 15:10nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fi fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ jú gbogbo wọn lọ, ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi.
- 1 Kọrinti 15:11nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà ìbá à ṣe èmí tàbí àwọn ni, èyí ní àwa wàásù, èyí ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́.
- 1 Kọrinti 15:12nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kristi pé ó tí jíǹde kúrò nínú òkú, èéha tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín fi wí pé, àjíǹde òkú kò sí.