- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Ẹkún Jeremiah 4:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀; kò sí bojútó wọn mọ́. Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbàgbà.
- Ẹkún Jeremiah 4:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Síwájú sí i, ojú wa kùnà fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán; láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.
- Ẹkún Jeremiah 4:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri, àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́. Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye nítorí òpin wa ti dé.
- Ẹkún Jeremiah 4:19nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn tí ń lé wa yára ju idì ojú ọ̀run lọ; wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù.
- Ẹkún Jeremiah 4:20nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ẹni àmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa, ni wọ́n fi tàkúté wọn mú. Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.
- Ẹkún Jeremiah 4:21nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Edomu, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Usi. Ṣùgbọ́n, a ó gbé ago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú; ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòhò.
- Ẹkún Jeremiah 4:22nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin; kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yà yóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.
- Ẹkún Jeremiah 5:1nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa; wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.
- Ẹkún Jeremiah 5:2nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì.
- Ẹkún Jeremiah 5:3nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó.
- Ẹkún Jeremiah 5:4nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa.
- Ẹkún Jeremiah 5:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa; àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.
- Ẹkún Jeremiah 5:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.
- Ẹkún Jeremiah 5:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
- Ẹkún Jeremiah 5:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa, kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.
- Ẹkún Jeremiah 5:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní aginjù.
- Ẹkún Jeremiah 5:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀.
- Ẹkún Jeremiah 5:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni, àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.
- Ẹkún Jeremiah 5:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn; kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.
- Ẹkún Jeremiah 5:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta; àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.
- Ẹkún Jeremiah 5:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn.
- Ẹkún Jeremiah 5:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa; ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
- Ẹkún Jeremiah 5:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Adé ti ṣí kúrò ní orí wa ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.
- Ẹkún Jeremiah 5:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa, nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.
- Ẹkún Jeremiah 5:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.