- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Ẹkún Jeremiah 3:57nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”
- Ẹkún Jeremiah 3:58nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.
- Ẹkún Jeremiah 3:59nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi. Gba ẹjọ́ mi ró!
- Ẹkún Jeremiah 3:60nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.
- Ẹkún Jeremiah 3:61nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,
- Ẹkún Jeremiah 3:62nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ sí mi ní gbogbo ọjọ́.
- Ẹkún Jeremiah 3:63nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.
- Ẹkún Jeremiah 3:64nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
- Ẹkún Jeremiah 3:65nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré.
- Ẹkún Jeremiah 3:66nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run Olúwa.
- Ẹkún Jeremiah 4:1nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù, wúrà dídára di àìdán! Òkúta ibi mímọ́ wá túká sí oríta gbogbo òpópó.
- Ẹkún Jeremiah 4:2nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye, tí wọ́n fi wúrà dídára ṣe wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!
- Ẹkún Jeremiah 4:3nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn bí ògòǹgò ní aginjù.
- Ẹkún Jeremiah 4:4nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn; àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn.
- Ẹkún Jeremiah 4:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára di òtòṣì ní òpópó. Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú.
- Ẹkún Jeremiah 4:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ìjìyà àwọn ènìyàn mi tóbi ju ti Sodomu lọ, tí a sí ní ipò ní òjijì láìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.
- Ẹkún Jeremiah 4:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí safire.
- Ẹkún Jeremiah 4:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú; wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó. Ara wọn hun mọ́ egungun; ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.
- Ẹkún Jeremiah 4:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn ju àwọn tí ìyàn pa; tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò fún àìní oúnjẹ láti inú pápá.
- Ẹkún Jeremiah 4:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ tí ó di oúnjẹ fún wọn nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.
- Ẹkún Jeremiah 4:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀; ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde. Ó da iná ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.
- Ẹkún Jeremiah 4:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́, tàbí àwọn ènìyàn ayé, wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ odi ìlú Jerusalẹmu.
- Ẹkún Jeremiah 4:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà, tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàrín rẹ̀.
- Ẹkún Jeremiah 4:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó bí ọkùnrin tí ó fọ́jú. Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.
- Ẹkún Jeremiah 4:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn. “Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!” Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé, “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”